Archive for September 28th, 2011

OMO YORUBA O FE PA EDE YORUBA O! ADALU YORUBA KODA!

September 28, 2011

PublicMrs.Yeye Akilimali Funua Olade
LATI OWO AGBEJORO OLANREWAJU Sikiru Adewoye-
YEYE AKILIMALI FUNUA OLADE
Eri maa je mi n so.Akojopo oruko Yeye gbodo mu royiroyi okan wa nipa n’ibo la ti bi won.Ibi ti a ti bi Yeye ko ja bi ise Oodua ti won gbe l’owo ti iseda ati awon alale Ile Yoruba si n fun won se.
Oro asa ati ise Yoruba kii se awada rara fun omo bibi Amerika ti eje adulawo fi ago ara re se ibugbe.Ko si ohun to ba Yeye l’okan je bi amulu…mola ede Yoruba.Bi Yeye se tutu ni iwa bi adaba to, won ko ri ara gba adalu ede Yoruba ati Geesi.Ede Yoruba ponbele je won l’ogun jojo.
Yeye k’apa okanjuwa won nipa oro(wealth) ati yodoyodo aye.Ko r’oro bee ko r’aago.Igbagbo ninu adura ni igba iponju mu won duro sinsin ninu Olorun.Bee won ko fi esin Kristi t’ako isese ati orisa.
Iranti iwa amunisin ati eleyameya ilu abinibi won ti da ogbe adaajiina si Yeye l’okan.Ikorira naa ga.
Ayafi ti ojumo ko ba mo ni Yeye ko ni ko si t’oke t’ile ofi ati ileke oniruhunru bi ojo iyawo.Ti ide owo ni ka so tabi t’ileke orun?T’ibadi nikan ni n ko mo.
Awon elerokero tile ro wipe imura yi ba amodi wa ni.Amodi l’ara taani?Opolo Yeye t’ohun ojogbon Fasiti egbera ni.Agbekale ati irori Yeye se apeere Alosi(leftee) gege bi olopolo pipe.
Yeye kii se aniyan ola bee ko fi ife awo dudu pamo.Ana Yeye meteeta l’okunrin dudu bi koro isin ni.Ibalopo ako ati ako ohun abo pelu abo ko Yeye ni irira ju ipaniyan lo.
Yeye ni ife aisetan.Olojuaanu ati onirele okan “Akata” ni.Bee alaafia won p’eye.Leyin odun kerinlelogota, irin ibuso ogorun ko jo Yeye l’oju.Ko m’eya, ko m’esin.Yeye f’eran iwe iroyin alaroye ati Tiwa n Tiwa ni kika.Won a si tun ra bun eniyan fun akagbadun.
Ni akotan, onkowe, onkawe, agb’asaga, olutunu, atunluse, ajajagbara, abiyamo ati oluko ni Oludari Ile iselojo iwe nipa ogun ati iwadi Adulawo to t’edo si aarin gbungbun Aba Adeyipo, Igbo Elerin, Ibadan.
LikeUnlike · · Share · 28 minutes ago near Lagos
Mrs.Yeye Akilimali Funua Olade FOR “OMO DUDU AMERIKKKA” ‘S SAKE THIS IS AN APPRECIATION FOR ALL I AM DOING TO SAVE YORUBA LANGUAGE! AN AWARD CEREMONY IN NIGERIA HAS CHOSEN ME ALONG WITH TRUE GIANTS TO HONOUR FOR THIS IN NOVEMBER! I LOVE AFRICA! I LOVE YORUBAS! THEY ALWAYS SHOW APPRECIATION FOR PEOPLE WHO WANT TO BUILD,EVEN IF THEY THEMSELVES HAVEN’T TAKEN THE TIME TO DO SOME BUILDING!


%d bloggers like this: