Archive for November 1st, 2019

Tribute to Me on my Birthday by Sukiru Adewoye o!

November 1, 2019

ÀJỌ̀DÚN ORÍKÁDÚN YÈYÉ AKILIMALI FUNUA ỌLÁDÉ
Olójà-Àṣà ti Ìlú Àṣà
Igba Ọdún ọdún kan ni o
Àjídèwe ni ti Eku Èlírí
À gbó ra kòrò ni ti Ahun
À gbó ra kòrò ni ti Ìgbín
Kí ẹ fi owó pá Ewú
Kí ẹ fi Èrìgì je Obì
Bí Eye Ológoṣé ba pe ní’gbó a da bi Èwe
Bí Kanranjángbọ́n bá f’enu mú’gi a tò ó d’òkè
Igba Ọdún ọdún kan fún Yèyé Akilimali Funua Olade
Yèyé Olójà-Àṣà pé ọdún Mẹ́rìndínlógórin l’Ókè Eèpè. Ọpé ni fún Adédàá. Kí ẹ ṣe ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọdún l’Áyé, l’Áàyè àti ní Ààyè Ìdèra pẹ̀lú Àlàáfíà.


%d bloggers like this: